1 : Ẹni tó ní agbádá, tàbí ẹni tó ń wọ agbádá: The owner of the agbádá or someone wearing it. f.a.: Bàbá alágbádá pupa yẹn ti dé. The man in the red agbádá has arrived.
2 : 1. Ẹni tó jẹ́ olóṣẹ̀lú tàbí tó ń darapọ̀ mọ́ awọn ìjọba àwa-ara-wa. 2. Ìjọba olóṣẹ̀lú: 1. A (civilian) politician. 2. Civil rule f.a.: Ìjọba alágbádá padà sí orílẹ̀ èdè wa ní ọdùn 1999. We returned to civilian rule in 1999.
3 : Oúnjẹ tí kò ní súgà, tàbí tí kò dùn.: A bland meal (particularly tea or other liquids) f.a.: "Tí mo bá mu tíì alágbádà lónìí, èyí kìí ṣe ìbànújẹ́ fún mi..." - Evang. Òjó Adé Drinking bland tea doesn't make me sad.
Most Popular